orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Solomoni 3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Mo wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́,lórí ibùsùn mi lálẹ́,mo wá a, ṣugbọn n kò rí i;mo pè é, ṣugbọn kò dáhùn.

2. N óo dìde nisinsinyii, n óo sì lọ káàkiri ìlú,n óo wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́,ní gbogbo òpópónà ati ní gbogbo gbàgede.Mo wá a ṣugbọn n kò rí i.

3. Àwọn aṣọ́de rí mi,bí wọ́n ṣe ń lọ káàkiri ìlú.Mo bèèrè lọ́wọ́ wọn pé,“Ǹjẹ́ ẹ rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́?”

4. Mo fẹ́rẹ̀ má tíì kúrò lọ́dọ̀ wọn,ni mo bá rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́.Mo dì í mú, n kò sì jẹ́ kí ó lọ,títí tí mo fi mú un dé ilé ìyá mi,ninu ìyẹ̀wù ẹni tí ó lóyún mi.

5. Mò ń kìlọ̀ fun yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,mo fi egbin ati àgbọ̀nrín inú igbó búra,pé, ẹ kò gbọdọ̀ jí olùfẹ́ mi, títí yóo fi wù ú láti jí.

Orin Kẹta

6. Kí ló ń jáde bọ̀ láti inú aṣálẹ̀ yìí,tí ó dàbí òpó èéfín,tí ó kún fún òórùn dídùn òjíá ati turari,pẹlu òórùn dídùn àtíkè àwọn oníṣòwò?

7. Wò ó! Solomoni ni wọ́n ń gbé bọ̀, lórí ìtẹ́ rẹ̀,ọgọta akọni ọkunrin, lára àwọn akọni Israẹli,ni ó yí ìtẹ́ rẹ̀ ká.

8. Gbogbo wọn dira ogun pẹlu idà,akọni sì ni wọ́n lójú ogun.Olukuluku dira pẹlu idà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, nítorí ìdágìrì ọ̀gànjọ́.

9. Igi Lẹbanoni ni Solomoni fi ṣe ìtẹ́ rẹ̀.

10. Ó fi fadaka ṣe àwọn ẹsẹ̀ ìjókòó rẹ̀,ó fi wúrà ṣe ẹ̀yìn rẹ̀,Aṣọ elése-àlùkò tí àwọn ọmọbinrin Jerusalẹmu hun ni ó fi ṣe tìmùtìmù ìjókòó rẹ̀.