5. Ẹ fi hapu kọ orin ìyìn sí OLUWA,àní, hapu ati ohùn orin dídùn.
6. Ẹ fun fèrè ati ìwokí ẹ sì hó ìhó ayọ̀ níwájú OLUWA Ọba.
7. Kí òkun ó hó, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀,kí ayé hó, ati àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
8. Omi òkun, ẹ pàtẹ́wọ́;kí ẹ̀yin òkè sì fi ayọ̀ kọrin pọ̀
9. níwájú OLUWA, nítorí pé ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé.Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé;yóo sì fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan.