Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 98:4-9 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Gbogbo ayé, ẹ hó ìhó ayọ̀ sí OLUWA;ẹ bú sí orin ayọ̀, kí ẹ sì kọ orin ìyìn.

5. Ẹ fi hapu kọ orin ìyìn sí OLUWA,àní, hapu ati ohùn orin dídùn.

6. Ẹ fun fèrè ati ìwokí ẹ sì hó ìhó ayọ̀ níwájú OLUWA Ọba.

7. Kí òkun ó hó, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀,kí ayé hó, ati àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

8. Omi òkun, ẹ pàtẹ́wọ́;kí ẹ̀yin òkè sì fi ayọ̀ kọrin pọ̀

9. níwájú OLUWA, nítorí pé ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé.Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé;yóo sì fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 98