Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 97:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA jọba, kí ayé ó yọ̀;jẹ́ kí inú ogunlọ́gọ̀ erékùṣù ó dùn.

2. Ìkùukùu ati òkùnkùn biribiri ni ó yí i ká;òdodo ati ẹ̀tọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀.

3. Iná ń jó lọ níwájú rẹ̀,ó sì ń jó àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́tùn-ún lósì.

4. Mànàmáná rẹ̀ tan ìmọ́lẹ̀ sí ayé,ilẹ̀ ayé rí i, ó sì wárìrì.

5. Àwọn òkè ńlá yọ́ bí ìda níwájú OLUWA,àní, níwájú OLUWA gbogbo ayé.

6. Ojú ọ̀run ń kéde òdodo rẹ̀;gbogbo orílẹ̀-èdè sì ń wo ògo rẹ̀.

7. Ojú ti gbogbo àwọn tí ń bọ oriṣa,àwọn tí ń fi ère lásánlàsàn yangàn;gbogbo oriṣa ní ń foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀.

8. Àwọn ará Sioni gbọ́, inú wọn dùn.Àwọn ará ìlú Juda sì ń yọ̀,nítorí ìdájọ́ rẹ, OLUWA.

9. Nítorí ìwọ OLUWA ni Ọ̀gá Ògo,o ju gbogbo ayé lọ,a gbé ọ ga ju gbogbo oriṣa lọ.

10. Ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn OLUWA, ẹ kórìíra ibi;OLUWA á máa dá ẹ̀mí àwọn olùfọkànsìn rẹ̀ sí,a sì máa gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú.

11. Ìmọ́lẹ̀ á máa tàn fún àwọn olódodo,ayọ̀ sì wà fún àwọn olótìítọ́ inú.

12. Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA, ẹ̀yin olódodo,kí ẹ sì máa yin orúkọ mímọ́ rẹ̀.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 97