Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 96:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ kọ orin titun sí OLUWA;gbogbo ayé, ẹ kọ orin sí OLUWA.

2. Ẹ kọ orin sí OLUWA, ẹ yin orúkọ rẹ̀;ẹ sọ nípa ìgbàlà rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́.

3. Ẹ kéde ògo rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè;ẹ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrin àwọn eniyan.

4. Nítorí OLUWA tóbi, ó yẹ kí á máa yìn ín lọpọlọpọ;ó sì yẹ kí á bẹ̀rù rẹ̀ ju gbogbo oriṣa lọ.

5. Nítorí oriṣa lásán ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ń sìn,ṣugbọn OLUWA ni ó dá ọ̀run.

6. Iyì ati ọlá ńlá ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀;agbára ati ẹwà kún inú ilé mímọ́ rẹ̀.

7. Ẹ yin OLUWA, gbogbo ẹ̀yin aráyé;ẹ kókìkí ògo ati agbára rẹ̀.

8. Ẹ fún OLUWA ní iyì tí ó tọ́ sí orúkọ rẹ̀,ẹ mú ọrẹ lọ́wọ́ wá sinu àgbàlá rẹ̀.

9. Ẹ sin OLUWA ninu ẹwà ìwà mímọ́;gbogbo ayé, ẹ wárìrì níwájú rẹ̀.

10. Ẹ wí láàrin àwọn orílẹ̀-èdè pé, “OLUWA jọba!A ti fi ìdí ayé múlẹ̀, kò sì ní yẹ̀ lae;OLUWA yóo fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan.”

11. Jẹ́ kí inú ọ̀run ó dùn, sì jẹ́ kí ayé ó yọ̀;kí òkun ó hó, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀.

12. Jẹ́ kí pápá oko ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ yọ̀.Nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóo fi ayọ̀ kọrin,

13. níwájú OLUWA, nítorí pé ó ń bọ̀;ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé.Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé;yóo sì fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 96