Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 95:2-11 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ẹ jẹ́ kí á wá siwaju rẹ̀ pẹlu ọpẹ́;ẹ jẹ́ kí á fi orin ìyìn hó ìhó ayọ̀ sí i.

3. Nítorí pé Ọlọrun tí ó tóbi ni OLUWA,ọba tí ó tóbi ni, ó ju gbogbo oriṣa lọ.

4. Ìkáwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà;gíga àwọn òkè ńlá wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ pẹlu.

5. Tirẹ̀ ni òkun, nítorí pé òun ni ó dá a;ọwọ́ rẹ̀ ni ó sì fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.

6. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á jọ́sìn, kí á tẹríba,ẹ jẹ́ kí á kúnlẹ̀ níwájú OLUWA, Ẹlẹ́dàá wa!

7. Nítorí òun ni Ọlọrun wa,àwa ni eniyan rẹ̀, tí ó ń kó jẹ̀ káàkiri,àwa ni agbo aguntan rẹ̀.Bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀ lónìí,

8. ẹ má ṣe orí kunkun bí ẹ ti ṣe ní Meriba,ati bí ẹ ti ṣe ní ijọ́un ní Masa, ninu aṣálẹ̀

9. nígbà tí àwọn baba ńlá yín dán mi wò,tí wọ́n dẹ mí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ríohun tí mo ti ṣe rí.

10. Fún ogoji ọdún gbáko ni ọ̀rọ̀ wọn fi sú mi,tí mo sọ pé, “Ọkàn àwọn eniyan wọnyi ti yapa,wọn kò sì bìkítà fún ìlànà mi.”

11. Nítorí náà ni mo fi fi ibinu búra pé,wọn kò ní wọ inú ìsinmi mi.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 95