Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 95:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á kọrin sí OLUWA;ẹ jẹ́ kí á hó ìhó ayọ̀ sí Olùdáàbòbò ati ìgbàlà wa!

2. Ẹ jẹ́ kí á wá siwaju rẹ̀ pẹlu ọpẹ́;ẹ jẹ́ kí á fi orin ìyìn hó ìhó ayọ̀ sí i.

3. Nítorí pé Ọlọrun tí ó tóbi ni OLUWA,ọba tí ó tóbi ni, ó ju gbogbo oriṣa lọ.

4. Ìkáwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà;gíga àwọn òkè ńlá wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ pẹlu.

5. Tirẹ̀ ni òkun, nítorí pé òun ni ó dá a;ọwọ́ rẹ̀ ni ó sì fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.

6. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á jọ́sìn, kí á tẹríba,ẹ jẹ́ kí á kúnlẹ̀ níwájú OLUWA, Ẹlẹ́dàá wa!

7. Nítorí òun ni Ọlọrun wa,àwa ni eniyan rẹ̀, tí ó ń kó jẹ̀ káàkiri,àwa ni agbo aguntan rẹ̀.Bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀ lónìí,

8. ẹ má ṣe orí kunkun bí ẹ ti ṣe ní Meriba,ati bí ẹ ti ṣe ní ijọ́un ní Masa, ninu aṣálẹ̀

Ka pipe ipin Orin Dafidi 95