Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 94:19-23 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Nígbà tí àìbàlẹ̀ ọkàn mi pọ̀ pupọ,ìwọ ni o tù mí ninu, tí o dá mi lọ́kàn le.

20. Ǹjẹ́ o lè ní àjọṣe pẹlu àwọn ìkà aláṣẹ,àwọn tí ń fi òfin gbé ìwà ìkà ró?

21. Wọ́n para pọ̀ láti gba ẹ̀mí olódodo;wọ́n sì dá ẹjọ́ ikú fún aláìṣẹ̀.

22. Ṣugbọn OLUWA ti di ibi ìsádi mi,Ọlọrun mi sì ti di àpáta ààbò mi.

23. Yóo san ẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún wọn,yóo pa wọ́n run nítorí ìwà ìkà wọn.OLUWA Ọlọrun wa yóo pa wọ́n run.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 94