Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 94:1-14 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, ìwọ Ọlọrun ẹ̀san,ìwọ Ọlọrun ẹ̀san, fi agbára rẹ hàn!

2. Dìde, ìwọ onídàájọ́ ayé;san ẹ̀san èrè iṣẹ́ àwọn agbéraga fún wọn!

3. OLUWA, yóo ti pẹ́ tó?Àní, yóo ti pẹ́ tó tí àwọn eniyan burúkú yóo máa ṣe jàgínní?

4. Wọ́n ń fi ìgbéraga sọ̀rọ̀ jàbùjàbù,gbogbo àwọn aṣebi ní ń fọ́nnu.

5. Wọ́n ń rún àwọn eniyan rẹ mọ́lẹ̀, OLUWA,wọ́n ń pọ́n àwọn eniyan rẹ lójú.

6. Wọ́n ń pa àwọn opó ati àwọn àlejò,wọ́n sì ń pa àwọn aláìníbaba;

7. wọ́n ń sọ pé, “OLUWA kò rí wa;Ọlọrun Jakọbu kò ṣàkíyèsí wa.”

8. Ẹ jẹ́ kí ó ye yín,ẹ̀yin tí ẹ ya òpè jùlọ láàrin àwọn eniyan!Ẹ̀yin òmùgọ̀, nígbà wo ni ẹ óo gbọ́n?

9. Ṣé ẹni tí ó dá etí, ni kò ní gbọ́ràn?Àbí ẹni tí ó dá ojú, ni kò ní ríran?

10. Ṣé ẹni tí ń jẹ àwọn orílẹ̀-èdè níyà,ni kò ní jẹ yín níyà?Àbí ẹni tí ń fún eniyan ní ìmọ̀, ni kò ní ní ìmọ̀?

11. OLUWA mọ èrò ọkàn ọmọ eniyan,ó mọ̀ pé afẹ́fẹ́ lásán ni.

12. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí o bá báwí, OLUWA,tí o sì kọ́ ní òfin rẹ,

13. kí ó lè sinmi lọ́wọ́ ọjọ́ ìṣòro,títí tí a ó fi gbẹ́ kòtò fún eniyan burúkú.

14. Nítorí OLUWA kò ní kọ àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀;kò ní ṣá àwọn eniyan ìní rẹ̀ tì;

Ka pipe ipin Orin Dafidi 94