Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 93:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA jọba; ó gbé ọlá ńlá wọ̀ bí ẹ̀wù;OLUWA gbé ọlá ńlá wọ̀,ó sì di agbára ni àmùrè.Ó fi ìdí ayé múlẹ̀;kò sì ní yẹ̀ laelae.

2. A ti fi ìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ láti ìgbà laelae;láti ayérayé ni o ti wà.

3. Ibú omi gbé ohùn wọn sókè, OLUWA,ibú omi gbé ohùn wọn sókè,ó sì ń sán bí ààrá.

4. OLUWA lágbára lókè!Ó lágbára ju ariwo omi òkun lọ,ó lágbára ju ìgbì omi òkun lọ.

5. Àwọn òfin rẹ kìí yipada,ìwà mímọ́ ni ó yẹ ilé rẹ títí lae, OLUWA.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 93