Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 92:10-15 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ṣugbọn o ti gbé mi ga, o ti fún mi lágbára bíi ti ẹfọ̀n;o ti da òróró dáradára sí mi lórí.

11. Mo ti fi ojú mi rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi,mo sì ti fi etí mi gbọ́ ìparun àwọn ẹni ibi tí ó gbé ìjà kò mí.

12. Àwọn olódodo yóo gbilẹ̀ bí igi ọ̀pẹ,wọn óo dàgbà bí igi kedari ti Lẹbanoni.

13. Wọ́n dàbí igi tí a gbìn sí ilé OLUWA,tí ó sì ń dàgbà ninu àgbàlá Ọlọrun wa.

14. Wọn á máa so èso títí di ọjọ́ ogbó wọn,wọn á máa lómi lára, ewé wọn á sì máa tutù nígbà gbogbo;

15. láti fihàn pé olóòótọ́ ni OLUWA;òun ni àpáta mi, kò sì sí aiṣododo lọ́wọ́ rẹ̀.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 92