Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 92:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ó dára kí eniyan máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, OLUWA;kí ó sì máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ, ìwọ Ọ̀gá Ògo;

2. ó dára kí eniyan máa kéde ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ní òwúrọ̀,kí ó máa kéde òtítọ́ rẹ ní alẹ́,

3. pẹlu orin, lórí ohun èlò orin olókùn mẹ́wàá,ati hapu.

4. Nítorí ìwọ, OLUWA, ti mú inú mi dùn nípa iṣẹ́ rẹ;OLUWA, mò ń fi ayọ̀ kọrin nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

5. Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tóbi pupọ, OLÚWA!Èrò rẹ sì jinlẹ̀ pupọ!

6. Òpè eniyan kò lè mọ̀,kò sì le yé òmùgọ̀:

7. pé bí eniyan burúkú bá tilẹ̀ rú bíi koríko,tí gbogbo àwọn aṣebi sì ń gbilẹ̀,ó dájú pé ìparun ayérayé ni òpin wọn.

8. Ṣugbọn ẹni àgbéga títí lae ni ọ́, OLUWA.

9. Wò ó, OLUWA, àwọn ọ̀tá rẹ yóo parun;gbogbo àwọn aṣebi yóo sì fọ́n ká.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 92