Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 91:8-16 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ojú nìkan ni óo kàn máa fi rí wọn,tí o óo sì máa fi wo èrè àwọn eniyan burúkú.

9. Nítorí tí ìwọ ti fi OLUWA ṣe ààbò rẹ,o sì ti fi Ọ̀gá Ògo ṣe ibùgbé rẹ,

10. ibi kankan kò ní dé bá ọ,bẹ́ẹ̀ ni àjálù kankan kò ní súnmọ́ ilé rẹ.

11. Nítorí yóo pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀, nítorí rẹ,pé kí wọ́n máa pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ.

12. Wọ́n óo fi ọwọ́ wọn gbé ọ sókè,kí o má baà fi ẹsẹ̀ gbún òkúta.

13. O óo rìn kọjá lórí kinniun ati paramọ́lẹ̀;ẹgbọ̀rọ̀ kinniun ati ejò ńlá ni o óo fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.

14. OLUWA ní, “Nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ sí mi,n óo gbà á là;n óo dáàbò bò ó, nítorí pé ó mọ orúkọ mi.

15. Yóo pè mí, n óo sì dá a lóhùn;n óo wà pẹlu rẹ̀ ninu ìṣòro,n óo yọ ọ́ ninu rẹ̀, n óo dá a lọ́lá.

16. N óo fi ẹ̀mí gígùn tẹ́ ẹ lọ́rùn,n óo sì gbà á là.”

Ka pipe ipin Orin Dafidi 91