Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 91:12-16 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Wọ́n óo fi ọwọ́ wọn gbé ọ sókè,kí o má baà fi ẹsẹ̀ gbún òkúta.

13. O óo rìn kọjá lórí kinniun ati paramọ́lẹ̀;ẹgbọ̀rọ̀ kinniun ati ejò ńlá ni o óo fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.

14. OLUWA ní, “Nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ sí mi,n óo gbà á là;n óo dáàbò bò ó, nítorí pé ó mọ orúkọ mi.

15. Yóo pè mí, n óo sì dá a lóhùn;n óo wà pẹlu rẹ̀ ninu ìṣòro,n óo yọ ọ́ ninu rẹ̀, n óo dá a lọ́lá.

16. N óo fi ẹ̀mí gígùn tẹ́ ẹ lọ́rùn,n óo sì gbà á là.”

Ka pipe ipin Orin Dafidi 91