Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 90:10-16 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Aadọrin ọdún ni ọjọ́ ayé wa;pẹlu ipá a lè tó ọgọrin;sibẹ gbogbo rẹ̀ jẹ́ kìkì làálàá ati ìyọnu;kíá, ayé wa á ti dópin, ẹ̀mí wa á sì fò lọ.

11. Ta ló mọ agbára ibinu rẹ?Ta ló sì mọ̀ pé bí ẹ̀rù rẹ ti tó bẹ́ẹ̀ ni ibinu rẹ rí?

12. Nítorí náà kọ́ wa láti máa ka iye ọjọ́ orí wa,kí á lè kọ́gbọ́n.

13. Yipada sí wa, OLUWA; yóo ti pẹ́ tó tí o óo máa bínú sí wa?Ṣàánú àwa iranṣẹ rẹ.

14. Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀,kí á lè máa yọ̀, kí inú wa sì máa dùnní gbogbo ọjọ́ ayé wa.

15. Mú inú wa dùn fún iye ọjọ́ tí oti fi pọ́n wa lójú,ati fún iye ọdún tí ojú wa ti fi rí ibi.

16. Jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ hàn sí àwọn iranṣẹ rẹ,kí agbára rẹ tí ó lógo sì hàn sí àwọn ọmọ wọn.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 90