Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 90:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, ìwọ ni o ti jẹ́ ibi ààbò wa láti ìrandíran.

2. Kí o tó dá àwọn òkè,ati kí o tó dá ilẹ̀ ati ayé,láti ayérayé, ìwọ ni Ọlọrun.

3. O sọ eniyan di erùpẹ̀ pada,o sì wí pé, “Ẹ yipada, ẹ̀yin ọmọ eniyan.”

4. Nítorí pé lójú rẹ, ẹgbẹrun ọdún dàbí àná,tabi bí ìṣọ́ kan ní òru.

5. Ìwọ a máa gbá ọmọ eniyan dànù; wọ́n dàbí àlá,bíi koríko tí ó tutù ní òwúrọ̀;

6. ní òwúrọ̀ á máa gbilẹ̀, á sì máa jí pérépéré;ní ìrọ̀lẹ́ á sá, á sì rọ.

7. Ibinu rẹ pa wá run;ìrúnú rẹ sì bò wá mọ́lẹ̀.

8. O ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa kalẹ̀ ní iwájú rẹ;àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀ wa sì hàn kedere ninu ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ.

9. Nítorí ọjọ́ ayé wa ń kọjá lọ ninu ibinu rẹ;ayé wa sì ń dópin bí ẹni mí kanlẹ̀.

10. Aadọrin ọdún ni ọjọ́ ayé wa;pẹlu ipá a lè tó ọgọrin;sibẹ gbogbo rẹ̀ jẹ́ kìkì làálàá ati ìyọnu;kíá, ayé wa á ti dópin, ẹ̀mí wa á sì fò lọ.

11. Ta ló mọ agbára ibinu rẹ?Ta ló sì mọ̀ pé bí ẹ̀rù rẹ ti tó bẹ́ẹ̀ ni ibinu rẹ rí?

Ka pipe ipin Orin Dafidi 90