Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 9:8-20 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé,yóo sì fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè.

9. OLUWA ni ààbò fún àwọn tí a ni lára,òun ni ibi ìsádi ní ìgbà ìpọ́njú.

10. Àwọn tí ó mọ̀ ọ́ yóo gbẹ́kẹ̀lé ọ;nítorí ìwọ, OLUWA, kìí kọ àwọn tí ń wá ọ sílẹ̀.

11. Ẹ kọrin ìyìn sí OLUWA, tí ó gúnwà ní Sioni!Ẹ kéde iṣẹ́ rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè!

12. Nítorí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ranti,kò sì gbàgbé igbe ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.

13. OLUWA, ṣàánú fún mi!Wò ó bí àwọn ọ̀tá mi ṣe ń pọ́n mi lójú.Gbà mí kúrò létí bèbè ikú,

14. kí n lè kọrin ìyìn rẹ,kí n sì lè yọ ayọ̀ ìgbàlà rẹ lẹ́nu ibodè Sioni.

15. Àwọn orílẹ̀-èdè ti jìn sinu kòtò tí wọ́n gbẹ́,wọ́n sì ti kó sinu àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀.

16. OLUWA ti fi ara rẹ̀ hàn, ó ti ṣe ìdájọ́,àwọn eniyan burúkú sì ti kó sinu tàkúté ara wọn.

17. Àwọn eniyan burúkú,àní, gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó gbàgbé Ọlọrun, ni yóo lọ sinu isà òkú.

18. Nítorí pé OLUWA kò ní fi ìgbà gbogbo gbàgbé àwọn aláìní,bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn talaka kò ní já sí òfo títí lae.

19. Dìde, OLUWA, má jẹ́ kí eniyan ó borí,jẹ́ kí á ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè níwájú rẹ.

20. OLUWA, da ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ bò wọ́n,jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé aláìlágbára eniyan ni àwọn.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 9