Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 89:31-48 BIBELI MIMỌ (BM)

31. bí wọ́n bá tàpá sí àṣẹ mi,tí wọn kò sì pa òfin mi mọ́;

32. n óo nà wọ́n lẹ́gba nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,n óo sì nà wọ́n ní pàṣán nítorí àìdára wọn.

33. Ṣugbọn ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ kò ní kúrò lára rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni n kò ní yẹ òtítọ́ mi.

34. N kò ni yẹ majẹmu mi,bẹ́ẹ̀ ni n kò ní yí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ pada.

35. “Níwọ̀n ìgbà tí mo ti fi ìwà mímọ́ mi búra:n kò ní purọ́ fún Dafidi.

36. Arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba títí lae,ìtẹ́ rẹ̀ yóo sì máa wà níwájú mi, níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ń yọ.

37. A óo fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ bí òṣùpá títí lae,yóo dúró ṣinṣin níwọ̀n ìgbà tí ojú ọ̀run bá ń bẹ.”

38. Ṣugbọn nisinsinyii inú rẹ ti ru sí ẹni àmì òróró rẹ;o ti ta á nù,o sì ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

39. O ti pa majẹmu tí o bá iranṣẹ rẹ dá tì,o ti ba adé rẹ̀ jẹ́, o ti fi wọ́lẹ̀.

40. O ti wó gbogbo odi rẹ̀;o sì ti sọ ilé ìṣọ́ rẹ̀ di ahoro.

41. Gbogbo àwọn tí ń kọjá lọ ní ń kó o lẹ́rù;ó ti di ẹni ẹ̀gàn lọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò rẹ̀.

42. O ti ran àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́;o ti mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ yọ̀ ọ́.

43. Àní, o ti ba gbogbo ohun ìjà rẹ̀ jẹ́,o kò sì ràn án lọ́wọ́ lójú ogun.

44. O ti gba ọ̀pá àṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀;o sì ti wó ìtẹ́ rẹ̀ palẹ̀.

45. O ti gé ìgbà èwe rẹ̀ kúrú;o sì ti da ìtìjú bò ó.

46. Yóo ti pẹ́ tó, OLUWA? Ṣé títí lae ni o óo máa fi ara pamọ́ fún mi?Yóo ti pẹ́ tó tí ibinu rẹ yóo máa jò bí iná?

47. OLUWA, ranti bí ọjọ́ ayé ẹ̀dá ti gùn mọ,ati pé ẹ̀dá lásán ni ọmọ eniyan!

48. Ta ló wà láyé tí kò ní kú?Ta ló lè gba ẹ̀mí ara rẹ̀ lọ́wọ́ agbára isà òkú?

Ka pipe ipin Orin Dafidi 89