Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 89:3-12 BIBELI MIMỌ (BM)

3. O sọ pé, “Mo ti dá majẹmu kan pẹluẹni tí mo yàn,mo ti búra fún Dafidi, iranṣẹ mi, pé,

4. ‘N óo fi ìdí àwọn ọmọ rẹ múlẹ̀ títí lae,n óo sì gbé ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’ ”

5. Jẹ́ kí ojú ọ̀run máa kọrin ìyìn iṣẹ́ ìyanu rẹ, OLÚWA;kí àwọn eniyan mímọ́ sì máa kọrin ìyìn òtítọ́ rẹ.

6. Nítorí ta ni a lè fi wé ọ ní ọ̀run, OLUWA?Ta ni ó dàbí OLUWA láàrin àwọn ẹ̀dá ọ̀run?

7. Ọlọrun, ìwọ ni a bẹ̀rù ninu ìgbìmọ̀ àwọn eniyan mímọ́,o tóbi, o sì lẹ́rù ju gbogbo àwọn tí ó yí ọ ká lọ?

8. OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, ta ló lágbára bíi rẹ?OLUWA, òtítọ́ rẹ yí ọ ká.

9. Ò ń jọba lórí òkun tí ń ru;nígbà tí ìgbì rẹ̀ bá ru sókè, ìwọ ni ò ń mú kí ó rọlẹ̀.

10. Ìwọ ni o wó Rahabu mọ́lẹ̀ bí òkú ẹran;o fi ọwọ́ agbára rẹ fọ́n àwọn ọ̀tá rẹ ká.

11. Tìrẹ ni ọ̀run, tìrẹ sì ni ayé pẹlu;ìwọ ni o tẹ ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ dó.

12. Ìwọ ni o dá àríwá ati gúsù,òkè Tabori ati òkè Herimoni ń fi ayọ̀yin orúkọ rẹ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 89