Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 89:15-34 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó mọ ìhó ayọ̀ nnì,àwọn tí ń rìn ninu ìmọ́lẹ̀ ojurere rẹ, OLUWA,

16. àwọn tí ń yọ̀ nítorí orúkọ rẹ tọ̀sán-tòru,tí sì ń gbé òdodo rẹ lárugẹ.

17. Nítorí ìwọ ni ògo ati agbára wọn;nípa ojurere rẹ sì ni a ti ní ìṣẹ́gun.

18. Dájúdájú, OLUWA, tìrẹ ni ààbò wa;ìwọ, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ọba wa.

19. Ní ìgbàanì, o sọ ninu ìran fún olùfọkànsìn rẹ pé,“Mo ti fi adé dé alágbára kan lórí,mo ti gbé ẹnìkan ga tí a yàn láàrin àwọn eniyan.

20. Mo ti rí Dafidi, iranṣẹ mi;mo ti fi òróró mímọ́ mi yàn án;

21. kí ọwọ́ agbára mi lè máa gbé e ró títí lae,kí ọwọ́ mi sì máa fún un ní okun.

22. Ọ̀tá kan kò ní lè borí rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan burúkú kò ní tẹ orí rẹ̀ ba.

23. N óo run ọ̀tá rẹ̀ níwájú rẹ̀;n óo sì bá àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ kanlẹ̀.

24. Òtítọ́ mi ati ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ yóo wà pẹlu rẹ̀;orúkọ mi ni yóo sì máa fi ṣẹgun.

25. N óo mú ìjọba rẹ̀ gbòòrò dé òkun;agbára rẹ̀ yóo sì tàn dé odò Yufurate

26. Yóo ké pè mí pé, ‘Ìwọ ni Baba mi,Ọlọrun mi, ati Àpáta ìgbàlà mi.’

27. N óo fi ṣe àkọ́bí,àní, ọba tí ó tóbi ju gbogbo ọba ayé lọ.

28. N óo máa fi ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ hàn án títí lae;majẹmu èmi pẹlu rẹ̀ yóo sì dúró ṣinṣin.

29. Arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba títí lae;ìtẹ́ rẹ̀ yóo sì máa bẹ níwọ̀n ìgbà tí ojú ọ̀run bá ń bẹ.

30. “Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá kọ òfin mi sílẹ̀,tí wọn kò sì tẹ̀lé ìlànà mi,

31. bí wọ́n bá tàpá sí àṣẹ mi,tí wọn kò sì pa òfin mi mọ́;

32. n óo nà wọ́n lẹ́gba nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,n óo sì nà wọ́n ní pàṣán nítorí àìdára wọn.

33. Ṣugbọn ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ kò ní kúrò lára rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni n kò ní yẹ òtítọ́ mi.

34. N kò ni yẹ majẹmu mi,bẹ́ẹ̀ ni n kò ní yí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ pada.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 89