Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 89:1-17 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, n óo máa kọrin ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ títí lae;n óo máa fi ẹnu mi kéde òtítọ́ rẹ láti ìran dé ìran.

2. Nítorí pé, a ti fi ìdí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ múlẹ̀ títí lae;o sì ti fi ìdí òtítọ́ rẹ múlẹ̀ bí ojú ọ̀run.

3. O sọ pé, “Mo ti dá majẹmu kan pẹluẹni tí mo yàn,mo ti búra fún Dafidi, iranṣẹ mi, pé,

4. ‘N óo fi ìdí àwọn ọmọ rẹ múlẹ̀ títí lae,n óo sì gbé ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’ ”

5. Jẹ́ kí ojú ọ̀run máa kọrin ìyìn iṣẹ́ ìyanu rẹ, OLÚWA;kí àwọn eniyan mímọ́ sì máa kọrin ìyìn òtítọ́ rẹ.

6. Nítorí ta ni a lè fi wé ọ ní ọ̀run, OLUWA?Ta ni ó dàbí OLUWA láàrin àwọn ẹ̀dá ọ̀run?

7. Ọlọrun, ìwọ ni a bẹ̀rù ninu ìgbìmọ̀ àwọn eniyan mímọ́,o tóbi, o sì lẹ́rù ju gbogbo àwọn tí ó yí ọ ká lọ?

8. OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, ta ló lágbára bíi rẹ?OLUWA, òtítọ́ rẹ yí ọ ká.

9. Ò ń jọba lórí òkun tí ń ru;nígbà tí ìgbì rẹ̀ bá ru sókè, ìwọ ni ò ń mú kí ó rọlẹ̀.

10. Ìwọ ni o wó Rahabu mọ́lẹ̀ bí òkú ẹran;o fi ọwọ́ agbára rẹ fọ́n àwọn ọ̀tá rẹ ká.

11. Tìrẹ ni ọ̀run, tìrẹ sì ni ayé pẹlu;ìwọ ni o tẹ ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ dó.

12. Ìwọ ni o dá àríwá ati gúsù,òkè Tabori ati òkè Herimoni ń fi ayọ̀yin orúkọ rẹ.

13. Alágbára ni ọ́;agbára ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;o gbé ọwọ́ agbára rẹ sókè.

14. Òdodo ati ẹ̀tọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ;ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ ń lọ ṣiwaju rẹ.

15. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ó mọ ìhó ayọ̀ nnì,àwọn tí ń rìn ninu ìmọ́lẹ̀ ojurere rẹ, OLUWA,

16. àwọn tí ń yọ̀ nítorí orúkọ rẹ tọ̀sán-tòru,tí sì ń gbé òdodo rẹ lárugẹ.

17. Nítorí ìwọ ni ògo ati agbára wọn;nípa ojurere rẹ sì ni a ti ní ìṣẹ́gun.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 89