Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 87:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní orí òkè mímọ́ ni ìlú tí OLUWA tẹ̀dó wà.

2. OLUWA fẹ́ràn ẹnubodè Sioni ju gbogbo ìlúyòókù lọ ní ilẹ̀ Jakọbu.

3. Ọpọlọpọ nǹkan tó lógo ni a sọ nípa rẹ,ìwọ ìlú Ọlọrun.

4. Tí mo bá ń ka àwọn ilẹ̀ tí ó mọ rírì mi,n óo dárúkọ Ijipti ati Babiloni,Filistia ati Tire, ati Etiopia.Wọn á máa wí pé, “Ní Jerusalẹmu ni wọ́n ti bí eléyìí.”

5. A óo wí nípa Sioni pé,“Ibẹ̀ ni a ti bí eléyìí ati onítọ̀hún,”nítorí pé Ọ̀gá Ògo yóo fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.

6. OLUWA yóo ṣírò rẹ̀ mọ́ wọnnígbà tí ó bá ń ṣe àkọsílẹ̀ àwọn eniyan rẹ̀ pé,“Ní Sioni ni a ti bí eléyìí.”

7. Àwọn akọrin ati àwọn afunfèrè ati àwọn tí ń jó yóo máa sọ pé,“Ìwọ, Sioni, ni orísun gbogbo ire wa.”

Ka pipe ipin Orin Dafidi 87