Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 86:11-17 BIBELI MIMỌ (BM)

11. OLUWA, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ,kí n lè máa rìn ninu òtítọ́ rẹ;kí n lè pa ọkàn pọ̀ láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.

12. Gbogbo ọkàn ni mo fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, OLUWA, Ọlọrun mi;n óo máa yin orúkọ rẹ lógo títí lae.

13. Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi sí mi;o ti yọ ọkàn mi kúrò ninu isà òkú.

14. Ọlọrun, àwọn agbéraga dìde sí mi;ẹgbẹ́ àwọn ìkà, aláìláàánú kan ń lépa ẹ̀mí mi;wọn kò sì bìkítà fún ọ.

15. Ṣugbọn ìwọ, OLUWA, ni Ọlọrun aláàánú ati olóore;o kì í tètè bínú, o sì kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́.

16. Kọjú sí mi, kí o sì ṣàánú mi;fún èmi iranṣẹ rẹ ní agbára rẹ;kí o sì gba èmi ọmọ iranṣẹbinrin rẹ là.

17. Fi àmì ojurere rẹ hàn mí,kí àwọn tí ó kórìíra mi lè rí i,kí ojú sì tì wọ́n;nítorí pé ìwọ, OLUWA, ni o ràn mí lọ́wọ́,tí o sì tù mí ninu.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 86