Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 86:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Tẹ́tí sí mi OLUWA, kí o sì gbọ́ adura mi,nítorí òtòṣì ati aláìní ni mí.

2. Dá ẹ̀mí mi sí nítorí olùfọkànsìn ni mí;gba èmi iranṣẹ rẹ tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ là;ìwọ ni Ọlọrun mi.

3. Ṣàánú mi, OLUWA,nítorí ìwọ ni mò ń kígbe pè tọ̀sán-tòru.

4. Mú inú iranṣẹ rẹ dùn,nítorí ìwọ ni mò ń gbadura sí.

5. Nítorí pé olóore ni ọ́, OLUWA,o máa ń dárí jini;ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀ sí gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́.

6. Fetí sí adura mi, OLUWA,gbọ́ igbe ẹ̀bẹ̀ mi.

7. Ní ọjọ́ ìpọ́njú mo ké pè ọ́,nítorí pé o máa ń gbọ́ adura mi.

8. OLUWA, kò sí èyí tí ó dàbí rẹ ninu àwọn oriṣa;kò sì sí iṣẹ́ ẹni tí ó dàbí iṣẹ́ rẹ.

9. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí o dá ni yóo wá,OLUWA, wọn óo máa forí balẹ̀ níwájú rẹ:wọn óo sì máa yin orúkọ rẹ lógo.

10. Nítorí pé o tóbi, o sì ń ṣe ohun ìyanu;ìwọ nìkan ni Ọlọrun.

11. OLUWA, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ,kí n lè máa rìn ninu òtítọ́ rẹ;kí n lè pa ọkàn pọ̀ láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.

12. Gbogbo ọkàn ni mo fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, OLUWA, Ọlọrun mi;n óo máa yin orúkọ rẹ lógo títí lae.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 86