Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 85:2-9 BIBELI MIMỌ (BM)

2. O dárí àìdára àwọn eniyan rẹ jì wọ́n;o sì bo gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.

3. O mú ìrúnú rẹ kúrò;o dáwọ́ ibinu gbígbóná rẹ dúró.

4. Tún mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun Olùgbàlà wa;dáwọ́ inú tí ń bí ọ sí wa dúró.

5. Ṣé o óo máa bínú sí wa títí lae ni?Ṣé ibinu rẹ yóo máa tẹ̀síwájú láti ìran dé ìran ni?

6. Ṣé o ò ní tún sọ wá jí ni,kí àwọn eniyan rẹ lè máa yọ̀ ninu rẹ?

7. Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn wá, OLUWA;kí o sì fún wa ní ìgbàlà rẹ.

8. Jẹ́ kí n gbọ́ ohun tí Ọlọrun, OLUWA yóo wí,nítorí pé ọ̀rọ̀ alaafia ni yóo sọ fún àwọn eniyan rẹ̀,àní, àwọn olùfọkànsìn rẹ̀,ṣugbọn kí wọn má yipada sí ìwà òmùgọ̀.

9. Nítòótọ́, ìgbàlà rẹ̀ wà nítòsí fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀;kí ògo rẹ̀ lè wà ní ilẹ̀ wa.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 85