Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 83:1-15 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọlọrun, má dákẹ́;má wòran; Ọlọrun má dúró jẹ́ẹ́!

2. Wò ó! Àwọn ọ̀tá rẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọ;àwọn tí ó kórìíra rẹ sì ń yájú sí ọ.

3. Wọ́n pète àrékérekè sí àwọn eniyan rẹ;wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀ sí àwọn tí ó sá di ọ́.

4. Wọ́n ní, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pa orílẹ̀-èdè wọn run;kí á má ranti orúkọ Israẹli mọ́!”

5. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jùmọ̀ pète pèrò;wọ́n dá majẹmu láti dojú kọ ọ́.

6. Àwọn ará Edomu, ati àwọn ọmọ Iṣimaeli,àwọn ará Moabu, ati àwọn ọmọ Hagiri,

7. àwọn ará Gebali, àwọn ọmọ Amoni, ati àwọn ọmọ Amaleki,àwọn ará Filistia ati àwọn tí ń gbé Tire.

8. Àwọn ará Asiria pàápàá ti dara pọ̀ mọ́ wọn;àwọn ni alátìlẹ́yìn àwọn ọmọ Lọti.

9. Ṣe wọ́n bí o ti ṣe àwọn ará Midiani,bí o ti ṣe Sisera ati Jabini ni odò Kiṣoni,

10. àwọn tí o parun ní Endori,tí wọ́n di ààtàn lórí ilẹ̀.

11. Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí o ti ṣe Orebu ati Seebu;ṣe àwọn ìjòyè wọn bí o ti ṣe Seba ati Salumuna,

12. àwọn tí ó wí pé,“Ẹ jẹ́ kí á mú lára ilẹ̀ Ọlọrunkí á sọ ọ́ di tiwa.”

13. Ọlọrun mi, ṣe wọ́n bí ààjà tíí ṣe ewé,àní, bí afẹ́fẹ́ tíí ṣe fùlùfúlù.

14. Bí iná tíí jó igbó,àní, bí ọwọ́ iná sì ṣe ń jó òkè kanlẹ̀,

15. bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ìjì rẹ lé wọn,kí o sì fi ààjà rẹ dẹ́rù bà wọ́n.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 83