Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 82:2-8 BIBELI MIMỌ (BM)

2. “Yóo ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin óo máa fi aiṣododo ṣe ìdájọ́,tí ẹ óo sì máa ṣe ojuṣaaju fún àwọn eniyan burúkú?

3. Ẹ ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn ọmọ aláìníbaba;ẹ sì máa ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn tí ojú ń pọ́n ati àwọn talaka.

4. Ẹ gba talaka ati aláìní sílẹ̀,ẹ gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú.”

5. Wọn kò ní ìmọ̀ tabi òye,wọ́n ń rìn kiri ninu òkùnkùn,títí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé fi mì tìtì.

6. Mo ní, “oriṣa ni yín,gbogbo yín ni ọmọ Ọ̀gá Ògo.

7. Ṣugbọn sibẹsibẹ, ẹ óo kú bí eniyan,ẹ ó sùn bí èyíkéyìí ninu àwọn ìjòyè.”

8. Dìde, Ọlọrun, ṣe ìdájọ́ ayé,nítorí tìrẹ ni gbogbo orílẹ̀-èdè!

Ka pipe ipin Orin Dafidi 82