Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 81:9-16 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Kò gbọdọ̀ sí ọlọrun àjèjì kan kan láàrin yín;ẹ kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún oriṣa-koriṣa kan.

10. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín,tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti.Ẹ ya ẹnu yín dáradára, n óo sì bọ yín ní àbọ́yó.

11. “Ṣugbọn àwọn eniyan mi kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu,Israẹli kò sì gba tèmi.

12. Nítorí náà mo fi wọ́n sílẹ̀ sinu agídí ọkàn wọn,kí wọn máa ṣe ohun tó wù wọ́n.

13. Àwọn eniyan mi ìbá jẹ́ gbọ́ tèmi,àní Israẹli ìbá jẹ́ máa rìn ní ọ̀nà mi!

14. Kíákíá ni èmi ìbá kọjú ìjà sí àwọn ọ̀tá wọn,tí ǹ bá sì ṣẹgun wọn.

15. Àwọn tí ó kórìíra OLUWA yóo fi ìbẹ̀rùbojo tẹríba fún un,ìyà óo sì jẹ wọ́n títí lae.

16. Ṣugbọn èmi ó máa fi ọkà tí ó dára jùlọ bọ yín,n óo sì fi oyin inú àpáta tẹ yín lọ́rùn.”

Ka pipe ipin Orin Dafidi 81