Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 81:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ kọ orin sókè sí Ọlọrun, agbára wa;ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọrun Jakọbu.

2. Ẹ dárin, ẹ lu samba, ẹ ta hapu dídùn ati lire.

3. Ẹ fọn fèrè ní ọjọ́ oṣù titun, ati níọjọ́ oṣù tí a yà sọ́tọ̀, ati ní ọjọ́ àsè.

4. Nítorí pé àṣẹ ni, fún àwọn ọmọ Israẹli,ìlànà sì ni, láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Jakọbu.

5. Ó pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Josẹfu,nígbà tí ó kọlu ilẹ̀ Ijipti.Mo gbọ́ ohùn kan tí n kò gbọ́ rí: tí ó wí pé,

6. “Mo ti sọ àjàgà náà kalẹ̀ lọ́rùn rẹ;mo ti gba agbọ̀n ẹrù kúrò lọ́wọ́ rẹ.

7. Ninu ìnira, o ké pè mí, mo sì gbà ọ́;mo dá ọ lóhùn ninu ìjì ààrá, níbi tí mo fara pamọ́ sí;mo sì dán ọ wò ninu omi odò Meriba.

8. Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan mi, nígbà tí mo báń kìlọ̀ fun yín,àní kí ẹ fetí sílẹ̀ sí mi, ẹ̀yin ọmọ Israẹli!

9. Kò gbọdọ̀ sí ọlọrun àjèjì kan kan láàrin yín;ẹ kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún oriṣa-koriṣa kan.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 81