Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 81:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ kọ orin sókè sí Ọlọrun, agbára wa;ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọrun Jakọbu.

2. Ẹ dárin, ẹ lu samba, ẹ ta hapu dídùn ati lire.

3. Ẹ fọn fèrè ní ọjọ́ oṣù titun, ati níọjọ́ oṣù tí a yà sọ́tọ̀, ati ní ọjọ́ àsè.

4. Nítorí pé àṣẹ ni, fún àwọn ọmọ Israẹli,ìlànà sì ni, láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Jakọbu.

5. Ó pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Josẹfu,nígbà tí ó kọlu ilẹ̀ Ijipti.Mo gbọ́ ohùn kan tí n kò gbọ́ rí: tí ó wí pé,

6. “Mo ti sọ àjàgà náà kalẹ̀ lọ́rùn rẹ;mo ti gba agbọ̀n ẹrù kúrò lọ́wọ́ rẹ.

7. Ninu ìnira, o ké pè mí, mo sì gbà ọ́;mo dá ọ lóhùn ninu ìjì ààrá, níbi tí mo fara pamọ́ sí;mo sì dán ọ wò ninu omi odò Meriba.

8. Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan mi, nígbà tí mo báń kìlọ̀ fun yín,àní kí ẹ fetí sílẹ̀ sí mi, ẹ̀yin ọmọ Israẹli!

9. Kò gbọdọ̀ sí ọlọrun àjèjì kan kan láàrin yín;ẹ kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún oriṣa-koriṣa kan.

10. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín,tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti.Ẹ ya ẹnu yín dáradára, n óo sì bọ yín ní àbọ́yó.

11. “Ṣugbọn àwọn eniyan mi kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu,Israẹli kò sì gba tèmi.

12. Nítorí náà mo fi wọ́n sílẹ̀ sinu agídí ọkàn wọn,kí wọn máa ṣe ohun tó wù wọ́n.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 81