Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 80:14-19 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Jọ̀wọ́ tún yipada, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun!Bojúwolẹ̀ láti ọ̀run, kí o sì wò ó;kí o sì tọ́jú ìtàkùn àjàrà yìí,

15. ohun ọ̀gbìn tí o fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbìn,àní, ọ̀dọ́ igi tí o fi ọwọ́ ara rẹ tọ́jú.

16. Àwọn ọ̀tá ti dáná sun ún, wọ́n ti gé e lulẹ̀;fi ojú burúkú wò wọ́n, kí wọ́n ṣègbé!

17. Ṣugbọn di ẹni tí o fúnra rẹ yàn mú,àní, ọmọ eniyan, tí o fúnra rẹ sọ di alágbára.

18. Ṣe bẹ́ẹ̀, a kò sì ní pada lẹ́yìn rẹ;dá wa sí, a ó sì máa sìn ọ́!

19. Mú wa bọ̀ sípò, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun!Fi ojurere wò wá, kí á lè là!

Ka pipe ipin Orin Dafidi 80