Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 80:1-16 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Dẹtí sílẹ̀, ìwọ olùṣọ́-aguntan Israẹli,Ìwọ tí ò ń tọ́jú àwọn ọmọ Josẹfu bí agbo ẹran.Ìwọ tí o gúnwà láàrin àwọn kerubu, yọ bí ọjọ́

2. níwájú Efuraimu ati Bẹnjamini ati Manase.Sọ agbára rẹ jí,kí o sì wá gbà wá là.

3. Mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun;fi ojurere wò wá,kí á le gbà wá là.

4. OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun,yóo ti pẹ́ tó, tí o óo máa bínú sí aduraàwọn eniyan rẹ?

5. O ti fi omijé bọ́ wọn bí oúnjẹ,o sì ti fún wọn ní omijé mu ní àmuyó.

6. O ti mú kí àwọn aládùúgbò wa máa jìjàdù lórí wa;àwọn ọ̀tá wa sì ń fi wá rẹ́rìn-ín láàrin ara wọn.

7. Mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun;fi ojurere wò wá,kí á lè là.

8. O mú ìtàkùn àjàrà kan jáde láti Ijipti;o lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde, o sì gbìn ín.

9. O ro ilẹ̀ fún un;ó ta gbòǹgbò wọlẹ̀, igi rẹ̀ sì gbilẹ̀.

10. Òjìji rẹ̀ bo àwọn òkè mọ́lẹ̀,ẹ̀ka rẹ sì bo àwọn igi kedari ńláńlá;

11. àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tàn kálẹ̀ títí kan òkun,àwọn èèhù rẹ̀ sì kan odò ńlá.

12. Kí ló dé tí o fi wó ògiri ọgbà rẹ̀,tí gbogbo àwọn tí ń kọjá lọsì fi ń ká èso rẹ̀?

13. Àwọn ìmàdò inú ìgbẹ́ ń jẹ ẹ́ ní àjẹrun,gbogbo àwọn nǹkan tí ń káàkiri ninu oko sì ń jẹ ẹ́.

14. Jọ̀wọ́ tún yipada, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun!Bojúwolẹ̀ láti ọ̀run, kí o sì wò ó;kí o sì tọ́jú ìtàkùn àjàrà yìí,

15. ohun ọ̀gbìn tí o fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbìn,àní, ọ̀dọ́ igi tí o fi ọwọ́ ara rẹ tọ́jú.

16. Àwọn ọ̀tá ti dáná sun ún, wọ́n ti gé e lulẹ̀;fi ojú burúkú wò wọ́n, kí wọ́n ṣègbé!

Ka pipe ipin Orin Dafidi 80