Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 8:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, Oluwa wa,orúkọ rẹ níyìn pupọ ní gbogbo ayé!Ìwọ ni o gbé ògo rẹ kalẹ̀ lókè ọ̀run.

2. Àwọn ọmọ-ọwọ́ ati àwọn ọmọ-ọmú ń kọrin ògo rẹ,wọ́n ti fi ìdí agbára rẹ múlẹ̀,nítorí àwọn tí ó kórìíra rẹ,kí á lè pa àwọn ọ̀tá ati olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́.

3. Nígbà tí mo ṣe akiyesi ojú ọ̀run, iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀, tí o sọlọ́jọ̀–

4. Kí ni eniyan jẹ́, tí o fi n náání rẹ̀?Àní, kí ni ọmọ eniyan, tí o fi ń ṣìkẹ́ rẹ̀?

5. O dá a, ipò rẹ̀ rẹlẹ̀ díẹ̀ sí ti ìwọ Ọlọrun,o sì ti fi ògo ati ọlá dé e ní adé.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 8