Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 78:8-22 BIBELI MIMỌ (BM)

8. kí wọn má dàbí àwọn baba ńlá wọn,ìran àwọn olóríkunkun ati ọlọ̀tẹ̀,àwọn tí ọkàn wọn kò dúró ṣinṣin,tí ẹ̀mí wọn kò sì dúró gbọningbọnin ti Olodumare.

9. Àwọn ọmọ Efuraimu kó ọrun, wọ́n kó ọfà,ṣugbọn wọ́n pẹ̀yìndà lọ́jọ́ ìjà.

10. Wọn kò pa majẹmu Ọlọrun mọ́,wọ́n kọ̀, wọn kò jẹ́ pa òfin rẹ̀ mọ́.

11. Wọ́n gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀,ati iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe hàn wọ́n.

12. Ní ìṣojú àwọn baba ńlá wọn, ó ṣe ohun ìyanu,ní ilẹ̀ Ijipti, ní oko Soani.

13. Ó pín òkun níyà, ó jẹ́ kí wọ́n kọjá láàrin rẹ̀;ó sì mú kí omi nàró bí òpó ńlá.

14. Ó fi ìkùukùu ṣe atọ́nà wọn ní ọ̀sán,ó fi ìmọ́lẹ̀ iná tọ́ wọn sọ́nà ní gbogbo òru.

15. Ó la àpáta ni aṣálẹ̀,ó sì fún wọn ní omi mu lọpọlọpọ bí ẹni pé láti inú ibú.

16. Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta;ó sì mú kí ó ṣàn bí odò.

17. Sibẹsibẹ wọn ò dẹ́kun ẹ̀ṣẹ̀ dídá;wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá Ògo ninu aṣálẹ̀.

18. Wọ́n dán Ọlọrun wò ninu ọkàn wọn,wọ́n ń wá oúnjẹ tí yóo tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn.

19. Wọ́n sọ̀rọ̀ ìwọ̀sí sí Ọlọrun, wọ́n ní,“Ṣé Ọlọrun lè gbé oúnjẹ kalẹ̀ fún wa ninu aṣálẹ̀?

20. Lóòótọ́ ó lu òkúta tí omi fi tú jáde,tí odò sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn.Ṣé ó lè fún wa ní òkèlè pẹlu,àbí ó lè pèsè ẹran fún àwọn eniyan rẹ̀?”

21. Nítorí náà nígbà tí OLUWA gbọ́,inú bí i;iná mọ́ ìdílé Jakọbu,inú OLUWA sì ru sí àwọn ọmọ Israẹli;

22. nítorí pé wọn kò gba Ọlọrun gbọ́;wọn kò sì gbẹ́kẹ̀lé agbára ìgbàlà rẹ̀.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 78