Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 78:6-16 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Kí àwọn ìran tí ń bọ̀ lè mọ̀ ọ́n,àní, àwọn ọmọ tí a kò tíì bí,kí àwọn náà ní ìgbà tiwọnlè sọ ọ́ fún àwọn ọmọ wọn.

7. Kí wọn lè gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun,kí wọn má gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀,kí wọn sì máa pa òfin rẹ̀ mọ́,

8. kí wọn má dàbí àwọn baba ńlá wọn,ìran àwọn olóríkunkun ati ọlọ̀tẹ̀,àwọn tí ọkàn wọn kò dúró ṣinṣin,tí ẹ̀mí wọn kò sì dúró gbọningbọnin ti Olodumare.

9. Àwọn ọmọ Efuraimu kó ọrun, wọ́n kó ọfà,ṣugbọn wọ́n pẹ̀yìndà lọ́jọ́ ìjà.

10. Wọn kò pa majẹmu Ọlọrun mọ́,wọ́n kọ̀, wọn kò jẹ́ pa òfin rẹ̀ mọ́.

11. Wọ́n gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀,ati iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe hàn wọ́n.

12. Ní ìṣojú àwọn baba ńlá wọn, ó ṣe ohun ìyanu,ní ilẹ̀ Ijipti, ní oko Soani.

13. Ó pín òkun níyà, ó jẹ́ kí wọ́n kọjá láàrin rẹ̀;ó sì mú kí omi nàró bí òpó ńlá.

14. Ó fi ìkùukùu ṣe atọ́nà wọn ní ọ̀sán,ó fi ìmọ́lẹ̀ iná tọ́ wọn sọ́nà ní gbogbo òru.

15. Ó la àpáta ni aṣálẹ̀,ó sì fún wọn ní omi mu lọpọlọpọ bí ẹni pé láti inú ibú.

16. Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta;ó sì mú kí ó ṣàn bí odò.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 78