Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 77:1-16 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Mo ké pe Ọlọrun fún ìrànlọ́wọ́,mo kígbe pe Ọlọrun kí ó lè gbọ́ tèmi.

2. Ní ọjọ́ ìpọ́njú mi, mo wá OLUWA;ní òru, mo tẹ́wọ́ adura láìkáàárẹ̀,ṣugbọn n kò rí ìtùnú.

3. Mo ronú nípa Ọlọrun títí, mò ń kérora;mo ṣe àṣàrò títí, ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì.

4. OLUWA, o ò jẹ́ kí n dijú wò ní gbogbo òrumo dààmú tóbẹ́ẹ̀ tí n kò le sọ̀rọ̀.

5. Mo ranti ìgbà àtijọ́,mo ranti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn.

6. Mo ronú jinlẹ̀ lóru,mo ṣe àṣàrò, mo yẹ ọkàn mi wò.

7. Ṣé Ọlọrun yóo kọ̀ wá sílẹ̀ títí lae ni;àbí inú rẹ̀ kò tún ní dùn sí wa mọ́?

8. Ṣé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ti pin títí lae ni;àbí ìlérí rẹ̀ ti dópin patapata?

9. Ṣé Ọlọrun ti gbàgbé láti máa ṣoore ni;àbí ó ti fi ibinu pa ojú àánú rẹ̀ dé?

10. Nígbà náà ni mo wí pé, “Ohun tí ó bà mí lọ́kàn jẹ́ ni péỌ̀gá Ògo kò jẹ́wọ́ agbára mọ́.”

11. N óo ranti àwọn iṣẹ́ OLUWA,àní, n óo ranti àwọn iṣẹ́ ìyanu ìgbàanì.

12. N óo máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ;n óo sì máa ronú lórí àwọn iṣẹ́ ribiribi tí o ṣe.

13. Ọlọrun, mímọ́ ni ọ̀nà rẹ;oriṣa wo ni ó tó Ọlọrun wa?

14. Ìwọ ni Ọlọrun tí ń ṣe ohun ìyanu;o ti fi agbára rẹ hàn láàrin àwọn eniyan.

15. O ti fi agbára rẹ gba àwọn eniyan rẹ là;àní, àwọn ọmọ Jakọbu ati Josẹfu.

16. Nígbà tí omi òkun rí ọ, Ọlọrun,àní, nígbà tí omi òkun fi ojú kàn ọ́,ẹ̀rù bà á;ibú omi sì wárìrì.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 77