Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 76:8-12 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Láti ọ̀run wá ni o ti ń ṣe ìdájọ́,ẹ̀rù ba ayé, ayé sì dúró jẹ́ẹ́;

9. nígbà tí Ọlọrun dìde láti gbé ìdájọ́ kalẹ̀,láti gba gbogbo àwọn tí à ń nilára láyé sílẹ̀.

10. Dájúdájú ibinu eniyan yóo pada di ìyìn fún ọ;àwọn tí wọ́n bá sì bọ́ lọ́wọ́ ibinu rẹyóo ṣe àjọ̀dún rẹ.

11. Jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun rẹ, kí o sì mú un ṣẹ,kí gbogbo àwọn tí ó yí i ká mú ẹ̀bùn wáfún ẹni tí ó yẹ kí á bẹ̀rù.

12. Ẹni tí ń gba ẹ̀mí àwọn ìjòyè,tí ó ń ṣe ẹ̀rù ba àwọn ọba ayé.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 76