Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 76:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àwọn ará Juda mọ Ọlọrun,orúkọ rẹ̀ sì lọ́wọ̀ ní Israẹli.

2. Ilé rẹ̀ wà ní Salẹmu,ibùgbé rẹ̀ wà ní Sioni.

3. Níbẹ̀ ni ó ti ṣẹ́ ọfà ọ̀tá tí ń rọ̀jò,ati apata, ati idà, ati àwọn ohun ìjà ogun.

4. Ológo ni ọ́, ọlá rẹ sì pọ̀,ó ju ti àwọn òkè tí ó kún fún ẹran lọ.

5. A gba ìkógun lọ́wọ́ àwọn akikanju,wọ́n sun oorun àsùn-ùn-jí;àwọn alágbára kò sì le gbé ọwọ́ láti jà.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 76