Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 75:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Ọlọrun; a dúpẹ́.À ń kéde orúkọ rẹ,a sì ń ròyìn iṣẹ́ ribiribi tí o ṣe.

2. OLUWA ní, “Nígbà tí àkókò tí mo yà sọ́tọ̀ bá tó,n óo ṣe ìdájọ́ pẹlu àìṣojúṣàájú.

3. Nígbà tí ayé bá ń mì síhìn-ín sọ́hùn-ún,ati gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀;èmi a mú kí òpó rẹ̀ dúró wámúwámú.

4. Èmi a sọ fún àwọn tí ń fọ́nnu pé, ‘Ẹ yé fọ́nnu’;èmi a sì sọ fún àwọn eniyan burúkú pé, ‘Ẹ yé ṣe ìgbéraga.’

5. Ẹ má halẹ̀ ju bí ó ti yẹ lọ,ẹ má sì gbéraga.”

6. Nítorí pé kì í ṣe láti ìlà oòrùn,tabi láti ìwọ̀ oòrùn,bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í ṣe apá gúsù tabi àríwá ni ìgbéga tií wá.

7. Ọlọrun níí dájọ́ bí ó ti wù ú:á rẹ ẹnìkan sílẹ̀, á sì gbé ẹlòmíràn ga.

8. Ife kan wà ní ọwọ́ OLUWA,Ibinu Oluwa ló kún inú rẹ̀,ó ń ru bí ọtí àní bí ọtí tí a ti lú,yóo ṣẹ́ ninu rẹ̀;gbogbo àwọn eniyan burúkú ilẹ̀ ayé ni yóo sì mu ún,wọn óo mu ún tán patapata tòun ti gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 75