Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 73:10-26 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Nítorí náà, àwọn eniyan á yipada, wọn á fara mọ́ wọn,wọn á máa yìn wọ́n, láìbìkítà fún ibi tí wọn ń ṣe.

11. Wọn á máa wí pé, “Báwo ni Ọlọrun ṣe lè mọ̀?Ǹjẹ́ Ọ̀gá Ògo tilẹ̀ ní ìmọ̀?”

12. Ẹ wò ó! Ayé àwọn eniyan burúkú nìwọ̀nyí;ara dẹ̀ wọ́n nígbà gbogbo, ọrọ̀ wọn sì ń pọ̀ sí i.

13. Lásán ni gbogbo aáyan mi láti rí i pé ọkàn mi mọ́,tí mo sì yọwọ́-yọsẹ̀ ninu ibi.

14. Nítorí pé tọ̀sán-tòru ni mò ń rí ìyọnu;láràárọ̀ ni à ń jẹ mí níyà.

15. Bí mo bá ní, “N óo sọ̀rọ̀ báyìí,”n óo kó àwọn ọmọ rẹ ṣìnà.

16. Ṣugbọn nígbà tí mo rò bí nǹkan wọnyi ṣe lè yé mi,mo rí i pé iṣẹ́ tíí dáni lágara ni.

17. Àfi ìgbà tí mo wọ ibi mímọ́ Ọlọrun lọ,ni mo tó wá rí òye ìgbẹ̀yìn wọn.

18. Nítòótọ́ ibi tí ń yọ̀ ni ó gbé wọn lé,ó sì mú kí wọn ṣubú sinu ìparun.

19. Wò ó bí wọn ṣe parun lọ́gán,tí ìpayà sì gbá wọn lọ patapata.

20. Wọ́n dàbí àlá tíí pòórá nígbà tí eniyan bá ta jí.OLUWA, nígbà tí o bá jí gìrì, wọn óo pòórá.

21. Nígbà tí ọkàn mí bàjẹ́,tí ọ̀rọ̀ náà gbóná lára mi,

22. mo hùwà òmùgọ̀, n kò sì lóye,mo sì dàbí ẹranko lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ.

23. Sibẹsibẹ nígbà gbogbo ni mo wà lọ́dọ̀ rẹ;o sì di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.

24. Ò ń fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi sọ́nà;lẹ́yìn náà, o óo sì gbà mí sinu ògo.

25. Ta ni mo ní lọ́run lẹ́yìn rẹ?Kò sì sí ohun kan tí ó wù mí láyé yìí bíkòṣe ìwọ.

26. Àárẹ̀ lè mú ara ati ẹ̀mí mi,ṣugbọn Ọlọrun ni agbára ẹ̀mí mi,ati ìpín mi títí lae.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 73