Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 72:11-19 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Gbogbo àwọn ọba yóo máa wólẹ̀ fún un;gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì máa sìn ín.

12. Nítorí pé a máa gba talaka tí ó bá ké pè é sílẹ̀;a sì máa gba àwọn tí ìyà ń jẹ sílẹ̀,ati àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́.

13. A máa ṣíjú àánú wo àwọn aláìní ati talaka,a sì máa gba àwọn talaka sílẹ̀.

14. A máa gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn aninilára ati oníwà ipá,ẹ̀mí wọn sì ṣe iyebíye ní ojú rẹ̀.

15. Ẹ̀mí rẹ̀ yóo gùn,a óo máa fi wúrà Ṣeba ta á lọ́rẹ,a óo máa gbadura fún un nígbà gbogbo;a óo sì máa súre fún un tọ̀sán-tòru.

16. Ọkà yóo pọ̀ lóko,yóo máa mì lẹ̀gbẹ̀ lórí òkè;èso rẹ̀ yóo dàbí ti Lẹbanoni,eniyan yóo pọ̀ ní ìlú,bíi koríko ninu pápá.

17. Orúkọ ọba óo wà títí lae,òkìkí rẹ̀ óo sì máa kàn níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ń ràn;àwọn eniyan óo máa fi orúkọ rẹ̀ súre fún ara wọn,gbogbo orílẹ̀-èdè óo sì máa pè é ní olóríire.

18. Ẹni-ìyìn ni OLUWA Ọlọrun Israẹli,ẹni tí ó ń ṣe iṣẹ́ ìyanu tí ẹlòmíràn kò lè ṣe.

19. Ẹni ìyìn títí lae ni ẹni tí orúkọ rẹ̀ lókìkí,kí òkìkí rẹ̀ gba ayé kan!Amin! Amin.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 72