Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 71:3-14 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Máa ṣe àpáta ààbò fún mi,jẹ́ odi alágbára fún mi kí o sì gbà mí,nítorí ìwọ ni ààbò ati odi mi.

4. Ọlọrun mi, gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú,àwọn alaiṣootọ ati ìkà.

5. Nítorí ìwọ OLUWA, ni ìrètí mi,OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé láti ìgbà èwe mi.

6. Ìwọ ni mo gbára lé láti inú oyún;ìwọ ni o mú mi jáde láti inú ìyá mi.Ìwọ ni n óo máa yìn nígbà gbogbo.

7. Mo di ẹni àmúpòwe fún ọpọlọpọ eniyan,ṣugbọn ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.

8. Ẹnu mi kún fún ìyìn rẹ,ó kún fún ògo rẹ tọ̀sán-tòru.

9. Má ta mí nù ní ìgbà ogbó mi;má sì gbàgbé mi nígbà tí n kò bá lágbára mọ́.

10. Nítorí pé àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi,àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi ti pàmọ̀ pọ̀,

11. wọ́n ní, “Ọlọrun ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀;ẹ lé e, ẹ mú un;nítorí kò sí ẹni tí yóo gbà á sílẹ̀ mọ́.”

12. Ọlọrun, má jìnnà sí mi;yára, Ọlọrun mi, ràn mí lọ́wọ́!

13. Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn alátakò mi, kí wọn parun;kí ẹ̀gàn ati ìtìjú bo àwọn tí ń wá ìpalára mi.

14. Ní tèmi, èmi ó máa ní ìrètí nígbà gbogbo,n óo sì túbọ̀ máa yìn ọ́.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 71