Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 71:11-20 BIBELI MIMỌ (BM)

11. wọ́n ní, “Ọlọrun ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀;ẹ lé e, ẹ mú un;nítorí kò sí ẹni tí yóo gbà á sílẹ̀ mọ́.”

12. Ọlọrun, má jìnnà sí mi;yára, Ọlọrun mi, ràn mí lọ́wọ́!

13. Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn alátakò mi, kí wọn parun;kí ẹ̀gàn ati ìtìjú bo àwọn tí ń wá ìpalára mi.

14. Ní tèmi, èmi ó máa ní ìrètí nígbà gbogbo,n óo sì túbọ̀ máa yìn ọ́.

15. N óo máa ṣírò iṣẹ́ rere rẹ,n óo máa ròyìn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ tọ̀sán-tòru,nítorí wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí n kò lè mọ iye wọn.

16. N óo wá ninu agbára OLUWA Ọlọrun,n óo máa kéde iṣẹ́ òdodo rẹ, àní, iṣẹ́ òdodo tìrẹ nìkan.

17. Ọlọrun, láti ìgbà èwe mi ni o ti kọ́ mi,títí di òní ni mo sì ń polongo iṣẹ́ ìyanu rẹ,

18. Nisinsinyii tí mo ti dàgbà, tí ewú sì ti gba orí mi,Ọlọrun, má kọ̀ mí sílẹ̀,títí tí n óo fi ròyìn iṣẹ́ ńlá rẹ,àní, iṣẹ́ agbára rẹ, fún gbogbo àwọn ìran tí ń bọ̀.

19. Ọlọrun, iṣẹ́ òdodo rẹ kan ojú ọ̀run,ìwọ tí o ṣe nǹkan ńlá,Ọlọrun, ta ni ó dàbí rẹ?

20. O ti jẹ́ kí n rí ọpọlọpọ ìpọ́njú ńlá,ṣugbọn óo tún mú ìgbé ayé mi pada bọ̀ sípò;óo tún ti gbé mi dìde láti inú isà òkú.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 71