Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 70:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọlọrun, dákun, gbà mí,yára, OLUWA, ràn mí lọ́wọ́.

2. Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí wọn fẹ́ gba ẹ̀mí mikí ìdàrúdàpọ̀ bá wọn;jẹ́ kí á lé àwọn tí ń wá ìpalára mi pada sẹ́yìn,kí wọn sì tẹ́.

3. Jẹ́ kí jìnnìjìnnì boàwọn tí ń yọ̀ mí, tí ń ṣe jàgínní mi;kí wọn sì gba èrè ìtìjú.

4. Kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ máa yọ̀ nítorí rẹ,kí inú wọn sì máa dùn,kí àwọn tí ó fẹ́ràn ìgbàlà rẹ máa wí nígbà gbogbo pé,“Ọlọrun tóbi!”

5. Ṣugbọn ní tèmi, olùpọ́njú ati aláìní ni mí,yára wá sọ́dọ̀ mi, Ọlọrun!Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi ati olùgbàlà mi,má pẹ́ OLÚWA.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 70