Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 7:5-17 BIBELI MIMỌ (BM)

5. jẹ́ kí ọ̀tá ó lé mi bá,kí ó tẹ̀ mí pa,kí ó sì bo òkú mi mọ́ ilẹ̀ẹ́lẹ̀.

6. OLUWA, fi ibinu dìde!Gbéra, kí o bá àwọn ọ̀tá mi jà ninu ìrúnú wọn;jí gìrì, Ọlọrun mi; ìwọ ni o ti fi ìlànà òdodo lélẹ̀.

7. Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ayé ó rọ̀gbà yí ọ ká,kí o sì máa jọba lé wọn lórí láti òkè wá.

8. OLUWA ló ń ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ayé;dá mi láre, OLUWA, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi ati ìwà pípé mi.

9. Ìwọ Ọlọrun Olódodo, tí o mọ èrò ati ìfẹ́ inú eniyan,fi òpin sí ìwà ibi àwọn eniyan burúkú,kí o sì fi ìdí àwọn olódodo múlẹ̀.

10. Ọlọrun ni aláàbò mi,òun níí gba àwọn ọlọ́kàn mímọ́ là.

11. Onídàájọ́ òdodo ni Ọlọrun,a sì máa bínú sí àwọn aṣebi lojoojumọ.

12. Bí wọn kò bá yipada, Ọlọrun yóo pọ́n idà rẹ̀;ó ti tẹ ọrun rẹ̀, ó sì ti fi ọfà lé e.

13. Ó ti pèsè ohun ìjà ikú sílẹ̀,ó sì ti tọ́jú ọfà iná.

14. Wò ó, eniyan burúkú lóyún ibi, ó lóyún ìkà, ó sì bí èké.

15. Ó gbẹ́ kòtò,ó sì jìn sinu kòtò tí ó gbẹ́.

16. Ìkà rẹ̀ pada sórí ara rẹ̀,àní ìwà ipá rẹ̀ sì já lù ú ní àtàrí.

17. N óo fi ọpẹ́ tí ó yẹ fún OLUWA nítorí òdodo rẹ̀,n óo fi orin ìyìn kí OLUWA, Ọ̀gá Ògo.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 7