Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 7:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni mo sá di;gbà mí là, kí o sì yọ mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi.

2. Kí wọn má baà fà mí ya bíi kinniun,kí wọn máa wọ́ mi lọ láìsí ẹni tí ó lè gbà mí sílẹ̀.

3. OLUWA, Ọlọrun mi, bí mo bá ṣe nǹkan yìí,bí iṣẹ́ ibi bá ń bẹ lọ́wọ́ mi,

4. bí mo bá fi ibi san án fún olóore,tabi tí mo bá kó ọ̀tá mi lẹ́rú láìnídìí,

5. jẹ́ kí ọ̀tá ó lé mi bá,kí ó tẹ̀ mí pa,kí ó sì bo òkú mi mọ́ ilẹ̀ẹ́lẹ̀.

6. OLUWA, fi ibinu dìde!Gbéra, kí o bá àwọn ọ̀tá mi jà ninu ìrúnú wọn;jí gìrì, Ọlọrun mi; ìwọ ni o ti fi ìlànà òdodo lélẹ̀.

7. Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ayé ó rọ̀gbà yí ọ ká,kí o sì máa jọba lé wọn lórí láti òkè wá.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 7