Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 69:8-19 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Mo ti di àlejò lọ́dọ̀ àwọn arakunrin mi,mo sì di àjèjì lọ́dọ̀ àwọn ọmọ ìyá mi.

9. Nítorí pé ìtara ilé rẹ ni ó jẹ mí lógún,ìwọ̀sí àwọn tí ó ń pẹ̀gàn rẹ sì bò mí mọ́lẹ̀.

10. Nígbà tí mo fi omijé gbààwẹ̀,ó di ẹ̀gàn fún mi.

11. Nígbà tí mò ń wọ aṣọ ọ̀fọ̀,mo di ẹni àmúpòwe.

12. Èmi ni àwọn tí ń jókòó lẹ́nu ibodèfi ń ṣe ọ̀rọ̀ sọ;àwọn ọ̀mùtí sì ń fi mí ṣe orin kọ.

13. Ṣugbọn ní tèmi, OLUWA, ìwọ ni mò ń gbadura síní àkókò tí ó bá yẹ, Ọlọrun,ninu ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,ninu agbára ìgbàlà rẹ, Ọlọrun dá mi lóhùn.

14. Yọ mí ninu irà yìí, má jẹ́ kí n rì,gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.

15. Má jẹ́ kí ìgbì omi bò mí mọ́lẹ̀,kí ibú omi má gbé mi mì,kí isà òkú má sì padé mọ́ mi.

16. Dá mi lóhùn, OLUWA, nítorí ìfẹ́ rẹtí kì í yẹ̀ dára;fojú rere wò mí, gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ àánú rẹ.

17. Má ṣe fi ojú pamọ́ fún èmi, iranṣẹ rẹ,nítorí tí mo wà ninu ìdààmú,yára dá mi lóhùn.

18. Sún mọ́ mi, rà mí pada,kí o sì tú mi sílẹ̀ nítorí àwọn ọ̀tá mi!

19. O mọ ẹ̀gàn mi,o mọ ìtìjú ati àbùkù mi;o sì mọ gbogbo àwọn ọ̀tá mi.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 69