Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 69:32-36 BIBELI MIMỌ (BM)

32. Àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóo rí i,inú wọn yóo dùn;ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wá Ọlọrun, ẹ jẹ́ kí ọkàn yín sọjí.

33. Nítorí OLUWA a máa gbọ́ ti àwọn aláìní,kì í sìí kẹ́gàn àwọn eniyan rẹ̀ tí ó wà ní ìgbèkùn.

34. Jẹ́ kí ọ̀run ati ayé kí ó yìn ín,òkun ati gbogbo ohun tí ó ń rìn káàkiri ninu wọn.

35. Nítorí Ọlọrun yóo gba Sioni là;yóo sì tún àwọn ìlú Juda kọ́;àwọn iranṣẹ rẹ̀ yóo máa gbé inú rẹ̀,yóo sì di tiwọn.

36. Àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ rẹ̀ yóo jogún rẹ̀;àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ̀ yóo sì máa gbé inú rẹ̀.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 69