Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 69:25-34 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Kí ibùdó wọn ó di ahoro,kí ẹnikẹ́ni má sì gbé inú àgọ́ wọn.

26. Nítorí ẹni tí o ti kọlù ni wọ́n tún gbógun tì;ẹni tí o ti ṣá lọ́gbẹ́ ni wọ́n sì tún ń pọ́n lójú.

27. Fi ẹ̀sùn kún ẹ̀sùn wọn;má sì jẹ́ kí wọ́n rí ìdáláre lọ́dọ̀ rẹ.

28. Pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò ninu ìwé ìyè;kí á má sì kọ orúkọ wọn mọ́ ti àwọn olódodo.

29. Ojú ń pọ́n mi, mo sì ń jẹ̀rora;Ọlọrun, jẹ́ kí ìgbàlà rẹ gbé mi lékè!

30. Èmi ó fi orin yin orúkọ Ọlọrun;n óo fi ọpẹ́ gbé e ga.

31. Èyí yóo tẹ́ Ọlọrun lọ́rùn ju akọ mààlúù lọ,àní, akọ mààlúù tòun tìwo ati pátákò rẹ̀.

32. Àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóo rí i,inú wọn yóo dùn;ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wá Ọlọrun, ẹ jẹ́ kí ọkàn yín sọjí.

33. Nítorí OLUWA a máa gbọ́ ti àwọn aláìní,kì í sìí kẹ́gàn àwọn eniyan rẹ̀ tí ó wà ní ìgbèkùn.

34. Jẹ́ kí ọ̀run ati ayé kí ó yìn ín,òkun ati gbogbo ohun tí ó ń rìn káàkiri ninu wọn.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 69