Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Dafidi 69:13-27 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Ṣugbọn ní tèmi, OLUWA, ìwọ ni mò ń gbadura síní àkókò tí ó bá yẹ, Ọlọrun,ninu ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,ninu agbára ìgbàlà rẹ, Ọlọrun dá mi lóhùn.

14. Yọ mí ninu irà yìí, má jẹ́ kí n rì,gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.

15. Má jẹ́ kí ìgbì omi bò mí mọ́lẹ̀,kí ibú omi má gbé mi mì,kí isà òkú má sì padé mọ́ mi.

16. Dá mi lóhùn, OLUWA, nítorí ìfẹ́ rẹtí kì í yẹ̀ dára;fojú rere wò mí, gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ àánú rẹ.

17. Má ṣe fi ojú pamọ́ fún èmi, iranṣẹ rẹ,nítorí tí mo wà ninu ìdààmú,yára dá mi lóhùn.

18. Sún mọ́ mi, rà mí pada,kí o sì tú mi sílẹ̀ nítorí àwọn ọ̀tá mi!

19. O mọ ẹ̀gàn mi,o mọ ìtìjú ati àbùkù mi;o sì mọ gbogbo àwọn ọ̀tá mi.

20. Ẹ̀gàn ti mú kí inú mi bàjẹ́,tóbẹ́ẹ̀ tí ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sìmò ń retí àánú ṣugbọn kò sí;mò ń retí olùtùnú, ṣugbọn n kò rí ẹnìkan.

21. Iwọ ni wọ́n sọ di oúnjẹ fún mi,nígbà tí òùngbẹ sì ń gbẹ mí,ọtí kíkan ni wọ́n fún mi mu.

22. Jẹ́ kí tabili oúnjẹ tí wọ́n tẹ́ fún arawọn di ẹ̀bìtì fún wọn;kí àsè ẹbọ wọn sì di tàkúté.

23. Jẹ́ kí ojú wọn ṣú,kí wọn má lè ríran;kí gbogbo ara wọn sì máa gbọ̀n rìrì.

24. Rọ òjò ibinu rẹ lé wọn lórí,kí o sì jẹ́ kí wọ́n rí gbígbóná ibinu rẹ.

25. Kí ibùdó wọn ó di ahoro,kí ẹnikẹ́ni má sì gbé inú àgọ́ wọn.

26. Nítorí ẹni tí o ti kọlù ni wọ́n tún gbógun tì;ẹni tí o ti ṣá lọ́gbẹ́ ni wọ́n sì tún ń pọ́n lójú.

27. Fi ẹ̀sùn kún ẹ̀sùn wọn;má sì jẹ́ kí wọ́n rí ìdáláre lọ́dọ̀ rẹ.

Ka pipe ipin Orin Dafidi 69